lílo àkàbà — ǹjẹ́ o máa ń ṣe àyẹ̀wò wọ̀nyí tó lè dáàbò bò ẹ́
paul fẹ́ pààrọ̀ gílóòbù iná tó wà lóde ilé ẹ̀
ó tún fẹ́ nu àwọn fèrèsé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lọ́wọ́ ita — ó ti pẹ́ tíyàwó ẹ̀ ti ń sọ pé wọ́n ti dọ̀tí
àmọ́ ṣe ni paul ń fòní dónìí tó ń fọ̀la dọ́la
nítorí pé ó gbọ́dọ̀ lo àkàbà